6 Lẹ́yìn èyí, wọn óo fi awọ dídán bò ó, wọn óo tẹ́ aṣọ aláwọ̀ aró lé e, wọn yóo sì ti ọ̀pá tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.
7 “Wọn yóo da aṣọ aláwọ̀ aró bo tabili tí burẹdi ìfihàn máa ń wà lórí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọn yóo kó àwọn nǹkan wọnyi lé e lórí: àwọn àwo turari, àwọn àwokòtò, ati àwọn ìgò fún ọtí ìrúbọ. Burẹdi ìfihàn sì gbọdọ̀ wà lórí rẹ̀ nígbà gbogbo.
8 Lẹ́yìn náà, wọn yóo da aṣọ pupa ati awọ dídán bò ó. Wọn yóo sì ti igi tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.
9 “Wọn yóo fi aṣọ aláwọ̀ aró bo ọ̀pá fìtílà ati àwọn fìtílà rẹ̀ ati àwọn ohun tí à ń lò pẹlu rẹ̀ ati gbogbo ohun èlò òróró.
10 Wọn yóo sì fi awọ dídán dì wọ́n, wọn yóo sì gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn.
11 “Lẹ́yìn èyí, wọn óo da aṣọ aláwọ̀ aró bo pẹpẹ wúrà, wọn óo fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò ó, wọn óo sì ti igi tí a fi ń gbé e bọ̀ ọ́.
12 Wọn yóo di àwọn ohun èlò ìsìn yòókù sinu aṣọ aláwọ̀ aró kan, wọn yóo sì fi awọ ewúrẹ́ tí ń dán bò wọ́n, wọn óo gbé wọn ka orí igi tí a óo fi gbé wọn.