17 yóo da omi mímọ́ sinu àwo kan, yóo bù lára erùpẹ̀ ilẹ̀ Àgọ́ Àjọ sinu omi náà.
18 Lẹ́yìn náà, alufaa yóo mú obinrin náà wá siwaju OLUWA, yóo tú irun orí obinrin náà, yóo sì gbé ẹbọ ìrántí lé e lọ́wọ́, tíí ṣe ẹbọ ohun jíjẹ ti owú. Àwo omi kíkorò, tí ó ń mú ègún wá yóo sì wà lọ́wọ́ alufaa.
19 Nígbà náà ni alufaa yóo mú kí obinrin náà búra, yóo wí fún un pé, ‘Bí ọkunrin kankan kò bá bá ọ lòpọ̀, tí o kò sì ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ, ègún inú omi kíkorò yìí kò ní ṣe ọ́ ní ibi.
20 Ṣugbọn bí o bá tí ṣe alaiṣootọ sí ọkọ rẹ (níwọ̀n ìgbà tí o wà ní ilé rẹ̀), tí o sì ti sọ ara rẹ di aláìmọ́ nípa pé ọkunrin mìíràn bá ọ lòpọ̀,
21 kí OLUWA sọ ọ́ di ẹni ègún ati ẹni ìfibú láàrin àwọn eniyan rẹ̀. Kí OLUWA mú kí abẹ́ rẹ rà, kí ó sì mú kí ara rẹ wú.
22 Kí omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí wọ inú rẹ, kí ó mú kí inú rẹ wú, kí ó sì mú kí abẹ́ rẹ rà.’“Obinrin náà yóo sì dáhùn pé, ‘Amin, Amin.’
23 “Lẹ́yìn èyí, kí alufaa kọ ègún yìí sinu ìwé, kí ó sì fọ̀ ọ́ sinu abọ́ omi kíkorò náà.