Nọmba 6:9-15 BM

9 “Bí ẹnìkan bá kú lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ lójijì, tí ó sì ti ipa bẹ́ẹ̀ sọ orí rẹ̀ di aláìmọ́; yóo dúró fún ọjọ́ meje. Ní ọjọ́ keje tí í ṣe ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀, yóo fá irun orí rẹ̀.

10 Ní ọjọ́ kẹjọ, yóo mú àdàbà meji tabi ọmọ ẹyẹlé meji tọ alufaa wá ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ.

11 Alufaa yóo fi ọ̀kan rú ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, yóo fi ikeji rú ẹbọ sísun láti ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa fífi ara kan òkú; yóo sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà.

12 Lẹ́yìn náà ni ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, a kì yóo ka àwọn ọjọ́ tí ó ti lò ṣáájú nítorí pé ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti bàjẹ́ nítorí pé ó fi ara kan òkú. Yóo sì mú ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan tọ alufaa wá fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi.

13 “Èyí ni yóo jẹ́ òfin fún Nasiri: Nígbà tí ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé, yóo wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Àjọ

14 pẹlu àwọn ọrẹ tí ó fẹ́ fún OLUWA: ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ sísun; abo ọ̀dọ́ aguntan, ọlọ́dún kan, tí kò ní àbààwọ́n, fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ati àgbò kan tí kò ní àbààwọ́n fún ẹbọ alaafia,

15 pẹlu burẹdi agbọ̀n kan, tí kò ní ìwúkàrà ninu, ati burẹdi aládùn tí a fi ìyẹ̀fun dáradára, tí a fi òróró pò ṣe, ati burẹdi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà ninu, tí a ta òróró sí lórí, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ohun mímu.