Samuẹli Kinni 29:1-7 BM

1 Àwọn ará Filistia kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ sí Afeki, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì pa ibùdó sí etí orísun omi tí ó wà ní àfonífojì Jesireeli.

2 Bí àwọn ọba Filistini ti ń kọjá pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn ní ọgọọgọrun-un ati ẹgbẹẹgbẹrun, Dafidi ati àwọn ọkunrin rẹ̀ tò sẹ́yìn ọba Akiṣi.

3 Àwọn olórí ogun Filistini bèèrè pé, “Kí ni àwọn Heberu wọnyi ń ṣe níbí?”Akiṣi sì dá wọn lóhùn pé, “Ṣebí Dafidi, iranṣẹ Saulu ọba Israẹli nìyí, ó ti wà lọ́dọ̀ mi láti ìgbà pípẹ́, n kò tíì rí àṣìṣe kan lọ́wọ́ rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní yìí.”

4 Àwọn olórí ogun náà bínú sí i gidigidi, wọ́n ní, “Sọ fún un, kí ó pada síbi tí o fún un, kí ó má bá wa lọ sójú ogun, kí ó má baà dojú ìjà kọ wá. Kí ni ìwọ rò pé yóo fẹ́ fi bá oluwa rẹ̀ làjà? Ṣebí nípa pípa àwọn ọmọ ogun wa ni.

5 Àbí nítorí Dafidi yìí kọ́ ni àwọn ọmọbinrin Israẹli ṣe ń jó tí wọ́n sì ń kọrin pé,‘Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀,ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀?’ ”

6 Akiṣi pe Dafidi, ó sọ fún un pé, “Mo fi OLUWA ṣe ẹlẹ́rìí pé o jẹ́ olóòótọ́ sí mi, inú mi sì dùn sí i pé kí o bá mi lọ sójú ogun yìí, nítorí pé n kò tíì rí ẹ̀bi kan lọ́wọ́ rẹ láti ìgbà tí o ti dé ọ̀dọ̀ mi títí di òní. Ṣugbọn àwọn olórí ogun kò gbà pé kí o bá wa lọ.

7 Nítorí náà, jọ̀wọ́ pada ní alaafia, kí o má baà múnú bí wọn.”