10 Dafidi ati irinwo (400) eniyan sì ń lépa wọn lọ, ṣugbọn àwọn igba (200) eniyan tí àárẹ̀ mú kò lè la odò náà kọjá, wọ́n sì dúró sí etí odò.
11 Àwọn ọmọlẹ́yìn Dafidi rí ọmọkunrin ará Ijipti kan ninu oko, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Dafidi, wọ́n fún un ní oúnjẹ ati omi,
12 èso ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ ati ìdì àjàrà meji. Nígbà tí ó jẹun tán, ó ní agbára nítorí pé kò tíì jẹun, kò sì mu omi fún ọjọ́ mẹta sẹ́yìn.
13 Dafidi bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ta ni oluwa rẹ, níbo ni o sì ti wá?”Ó dáhùn pé, “Ará Ijipti ni mí, ẹrú ará Amaleki kan. Ọjọ́ kẹta nìyí tí oluwa mi ti fi mí sílẹ̀ níhìn-ín, nítorí pé ara mi kò dá.
14 A ti jagun ní Nẹgẹbu ní agbègbè Kereti ati ní agbègbè Juda ati ní agbègbè Nẹgẹbu ti Kalebu, a sì sun Sikilagi níná.”
15 Dafidi bi í léèrè pé, “Ṣé o lè mú mi lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ogun náà?”Ó dáhùn pé, “N óo mú ọ lọ, bí o bá ṣèlérí ní orúkọ Ọlọrun pé o kò ní pa mí, tabi kí o fi mí lé oluwa mi lọ́wọ́.”
16 Ó mú Dafidi lọ bá wọn.Àwọn ọmọ ogun náà fọ́n káàkiri, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n sì ń jó, nítorí ọpọlọpọ ìkógun tí wọ́n rí kó ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia ati Juda.