1 Bí ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí:
2 Gẹ́gẹ́ bí wolii Aisaya ti kọ ọ́ tẹ́lẹ̀ ni ó rí:“Ọlọrun ní,‘Wò ó! Mo rán oníṣẹ́ mi ṣiwaju rẹòun ni yóo palẹ̀ mọ́ dè ọ́.’
3 Ohùn ẹni tí ń kígbe ninu aṣálẹ̀ pé,‘Ẹ la ọ̀nà tí Oluwa yóo gbà,ẹ ṣe é kí ó tọ́ fún un láti rìn.’ ”
4 Báyìí ni Johanu bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìrìbọmi ninu aṣálẹ̀, tí ó ń waasu pé kí àwọn eniyan ronupiwada, kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, kí Ọlọrun lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n.
5 Gbogbo eniyan ilẹ̀ Judia ati ti ìlú Jerusalẹmu jáde tọ̀ ọ́ lọ, wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, ó sì ń ṣe ìrìbọmi fún wọn ninu odò Jọdani.
6 Irun ràkúnmí ni wọ́n fi hun aṣọ tí Johanu wọ̀, ọ̀já ìgbànú aláwọ ni ó gbà mọ́ ìdí, eṣú ni ó ń jẹ, ó sì ń lá oyin ìgàn.
7 Ó ń waasu pé, “Ẹnìkan tí ó jù mí lọ ń bọ̀ lẹ́yìn mi, n kò tó bẹ̀rẹ̀ láti tú okùn bàtà rẹ̀.