60 Nígbà náà ni Olórí Alufaa dìde láàrin wọn, ó bi Jesu pé, “Ìwọ kò fèsì rárá?”
61 Ṣugbọn ó sá dákẹ́ ni, kò fèsì kankan.Olórí Alufaa tún bi í pé, “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Olùbùkún?”
62 Jesu dáhùn pé, “Èmi ni. Ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.”
63 Olórí Alufaa bá fa ẹ̀wù rẹ̀ ya, ó ní, “Ẹlẹ́rìí wo ni a tún ń wá?
64 Ẹ ti gbọ́ tí ó sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọrun! Kí ni ẹ wí?”Gbogbo wọn bá dá a lẹ́bi, wọ́n ní ikú ni ó tọ́ sí i.
65 Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí tutọ́ sí i lára. Wọ́n fi aṣọ bò ó lójú, wọ́n wá ń sọ ọ́ ní ẹ̀ṣẹ́. Wọ́n sọ fún un pé, “Sọ ẹni tí ó lù ọ́ fún wa, wolii!” Àwọn iranṣẹ wá ń gbá a létí bí wọn ti ń mú un lọ sí àtìmọ́lé.
66 Nígbà tí Peteru wà ní ìsàlẹ̀ ní agbo-ilé, ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin Olórí Alufaa dé.