53 Nígbà tí wọ́n la òkun já, wọ́n dé Genesarẹti, wọ́n bá gúnlẹ̀.
54 Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ọkọ̀, lẹsẹkẹsẹ àwọn eniyan mọ̀ wọ́n.
55 Wọ́n bá ń súré láti gbogbo àdúgbò ibẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wọn lórí ibùsùn wá sí ibikíbi tí wọn bá gbọ́ pé Jesu wà.
56 Níbikíbi tí ó bá wọ̀, ìbáà ṣe ní abúlé tabi ninu ìlú, ní ìgbèríko, tabi ní ọjà, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wá. Wọn a máa bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn ṣá lè fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án pátá ni ó mú lára dá.