2 Awọn iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Jẹ ki a wá ọmọbinrin kan, wundia, fun Oluwa mi, ọba: ki o si duro niwaju ọba, ki o si ṣikẹ́ rẹ̀, ki o si dubulẹ li õkan-aiya rẹ̀, oluwa mi, ọba yio si mõru.
3 Nwọn si wá ọmọbinrin arẹwà kan ka gbogbo agbegbe Israeli, nwọn si ri Abiṣagi, ara Ṣunemu, nwọn si mu u tọ̀ ọba wá.
4 Ọmọbinrin na si ṣe arẹwà gidigidi, o si nṣikẹ́ ọba, o si nṣe iranṣẹ fun u; ṣugbọn ọba kò si mọ̀ ọ.
5 Adonijah, ọmọ Haggiti, si gbe ara rẹ̀ ga, wipe, emi ni yio jọba: o si mura kẹkẹ́ ati awọn ẹlẹṣin, ati ãdọta ọkunrin lati sare niwaju rẹ̀.
6 Baba rẹ̀ kò si bà a ninu jẹ rí, pe, Ẽṣe ti iwọ fi ṣe bayi? On si ṣe enia ti o dara gidigidi: iya rẹ̀ si bi i le Absalomu.
7 O si ba Joabu, ọmọ Seruiah, ati Abiatari, alufa gbèro: nwọn si nràn Adonijah lọwọ.
8 Ṣugbọn Sadoku alufa, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati Natani woli, ati Ṣimei, ati Rei, ati awọn ọkunrin alagbara ti mbẹ lọdọ Dafidi, kò wà pẹlu Adonijah.