12 Ṣugbọn emi ki yio ṣe e li ọjọ rẹ, nitori Dafidi baba rẹ; emi o fà a ya kuro lọwọ ọmọ rẹ.
13 Kiki pe emi kì yio fà gbogbo ijọba na ya; emi o fi ẹyà kan fun ọmọ rẹ, nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu ti mo ti yàn.
14 Oluwa si gbe ọta kan dide si Solomoni, Hadadi, ara Edomu: iru-ọmọ ọba li on iṣe ni Edomu.
15 O si ṣe, nigbati Dafidi wà ni Edomu, ati ti Joabu olori-ogun goke lọ lati sìn awọn ti a pa, nigbati o pa gbogbo ọkunrin ni Edomu.
16 Nitori oṣù mẹfa ni Joabu fi joko nibẹ ati gbogbo Israeli, titi o fi ké gbogbo ọkunrin kuro ni Edomu:
17 Hadadi si sá, on ati awọn ara Edomu ninu awọn iranṣẹ baba rẹ̀ pẹlu rẹ̀, lati lọ si Egipti; ṣugbọn Hadadi wà li ọmọde.
18 Nwọn si dide kuro ni Midiani, nwọn si wá si Parani; nwọn si mu enia pẹlu wọn lati Parani wá: nwọn si wá si Egipti, sọdọ Farao ọba Egipti, o si fun u ni ile kan, o si yàn onjẹ fun u, o si fun u ni ilẹ.