27 Eyi si ni idi ohun ti o ṣe gbe ọwọ soke si ọba: Solomoni kọ́ Millo, o si di ẹya ilu Dafidi baba rẹ̀.
28 Ọkunrin na, Jeroboamu, ṣe alagbara akọni: nigbati Solomoni si ri ọdọmọkunrin na pe, oṣiṣẹ enia ni, o fi i ṣe olori gbogbo iṣẹ-iru ile Josefu.
29 O si ṣe li àkoko na, nigbati Jeroboamu jade kuro ni Jerusalemu, woli Ahijah ara Ṣilo ri i loju ọ̀na; o si wọ̀ agbáda titun; awọn meji pere li o si mbẹ ni oko:
30 Ahijah si gbà agbáda titun na ti o wà lara rẹ̀, o si fà a ya si ọ̀na mejila:
31 O si wi fun Jeroboamu pe, Iwọ mu ẹya mẹwa: nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o fa ijọba na ya kuro li ọwọ Solomoni, emi o si fi ẹya mẹwa fun ọ.
32 Ṣugbọn on o ni ẹya kan nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn ninu gbogbo ẹya Israeli:
33 Nitori ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si mbọ Astoreti, oriṣa awọn ara Sidoni, ati Kemoṣi, oriṣa awọn ara Moabu, ati Milkomu, oriṣa awọn ọmọ Ammoni, nwọn kò si rin li ọ̀na mi, lati ṣe eyiti o tọ́ li oju mi, ati lati pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.