34 Ṣugbọn emi kì yio gba gbogbo ijọba na lọwọ rẹ̀, ṣugbọn emi o ṣe e li ọmọ-alade ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀, nitori Dafidi, iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn, nitori o ti pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́:
35 Ṣugbọn emi o gba ijọba na li ọwọ ọmọ rẹ̀, emi o si fi i fun ọ, ani ẹya mẹwa.
36 Emi o si fi ẹya kan fun ọmọ rẹ̀, ki Dafidi iranṣẹ mi ki o le ni imọlẹ niwaju mi nigbagbogbo, ni Jerusalemu, ilu ti mo ti yàn fun ara mi lati fi orukọ mi sibẹ.
37 Emi o si mu ọ, iwọ o si jọba gẹgẹ bi gbogbo eyiti ọkàn rẹ nfẹ, iwọ o si jẹ ọba lori Israeli.
38 Yio si ṣe, bi iwọ o ba tẹtisilẹ si gbogbo eyiti mo paṣẹ fun ọ, ti iwọ o mã rin li ọ̀na mi, ti iwọ o si mã ṣe eyiti o tọ́ loju mi, lati pa aṣẹ mi ati ofin mi mọ́, gẹgẹ bi Dafidi iranṣẹ mi ti ṣe; emi o si wà pẹlu rẹ, emi o si kọ́ ile otitọ fun ọ, gẹgẹ bi emi ti kọ́ fun Dafidi, emi o si fi Israeli fun ọ.
39 Emi o si pọ́n iru-ọmọ Dafidi loju nitori eyi, ṣugbọn kì iṣe titi lai.
40 Nitorina Solomoni wá ọ̀na lati pa Jeroboamu. Jeroboamu si dide, o si sá lọ si Egipti si ọdọ Ṣiṣaki ọba Egipti, o si wà ni Egipti titi ikú Solomoni.