15 Ọba kò si fi eti si ti awọn enia na; nitoriti ọ̀ran na ati ọwọ Oluwa wá ni, ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti Oluwa ti ọwọ Ahijah, ara Ṣilo, sọ fun Jeroboamu, ọmọ Nebati.
16 Bẹ̃ni nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kò fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba li ohùn wipe: Ipin kini awa ni ninu Dafidi? bẹ̃ni awa kò ni iní ninu ọmọ Jesse: Israeli, ẹ pada si agọ nyin: njẹ mã bojuto ile rẹ, Dafidi! Bẹ̃ni Israeli pada sinu agọ wọn.
17 Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli ti ngbe inu ilu Juda wọnni, Rehoboamu jọba lori wọn.
18 Nigbana ni Rehoboamu ọba, ran Adoramu ẹniti iṣe olori iṣẹ-iru; gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Nitorina Rehoboamu, ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀, lati sá lọ si Jerusalemu.
19 Bẹ̃ni Israeli ṣọtẹ̀ si ile Dafidi titi di oni yi.
20 O si ṣe nigbati gbogbo Israeli gbọ́ pe Jeroboamu tun pada bọ̀, ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pè e wá si ajọ, nwọn si fi i jọba lori gbogbo Israeli: kò si ẹnikan ti o tọ̀ ile Dafidi lẹhin, bikoṣe kiki ẹya Juda.
21 Nigbati Rehoboamu si wá si Jerusalemu, o ko gbogbo ile Juda jọ, pẹlu ẹya Benjamini, ọkẹ mẹsan enia ti a yàn, ti nwọn iṣe ologun, lati ba ile Israeli ja, lati mu ijọba na pada bọ̀ sọdọ Rehoboamu, ọmọ Solomoni.