4 Ṣugbọn nitori Dafidi li Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fun u ni imọlẹ kan ni Jerusalemu, lati gbé ọmọ rẹ̀ ró lẹhin rẹ̀, ati lati fi idi Jerusalemu mulẹ:
5 Nitori Dafidi ṣe eyi ti o tọ li oju Oluwa, kò si yipada kuro ninu gbogbo eyiti o paṣẹ fun u li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo, bikoṣe ni kiki ọ̀ran Uriah, ara Hitti.
6 Ogun si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu li ọjọ aiye rẹ̀ gbogbo.
7 Njẹ iyokù iṣe Abijah ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda? Ogun si wà lãrin Abijah ati Jeroboamu.
8 Abijah si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀; nwọn si sin i ni ilu Dafidi: Asa, ọmọ rẹ̀, si jọba ni ipò rẹ̀.
9 Ati li ogun ọdun Jeroboamu ọba Israeli, ni Asa jọba lori Juda.
10 Ọdun mọkanlelogoji li o jọba ni Jerusalemu, orukọ iya nla rẹ̀ si ni Maaka, ọmọbinrin Abiṣalomu.