1. A. Ọba 2:1-7 YCE

1 ỌJỌ Dafidi si sunmọ etile ti yio kú: o si paṣẹ fun Solomoni, ọmọ rẹ̀ pe:

2 Emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: nitorina mu ara rẹ le, ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ọkunrin.

3 Ki o si pa ilana Oluwa, Ọlọrun rẹ mọ, lati ma rin li ọ̀na rẹ̀, lati pa aṣẹ rẹ̀ mọ, ati ofin rẹ̀, ati idajọ, rẹ̀ ati ẹri rẹ̀ gẹgẹ bi a ti kọ ọ ni ofin Mose, ki iwọ ki o lè ma pọ̀ si i ni ohun gbogbo ti iwọ o ṣe, ati nibikibi ti iwọ ba yi ara rẹ si.

4 Ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ duro ti o ti sọ niti emi pe: Bi awọn ọmọ rẹ ba kiyesi ọ̀na wọn, lati mã fi gbogbo aiya wọn, ati gbogbo ọkàn wọn, rìn niwaju mi li otitọ, (o wipe), a kì yio fẹ ọkunrin kan kù fun ọ lori itẹ Israeli.

5 Iwọ si mọ̀ pẹlu, ohun ti Joabu, ọmọ Seruiah, ṣe si mi, ati ohun ti o ṣe si balogun meji ninu awọn ọgagun Israeli, si Abneri, ọmọ Neri, ati si Amasa, ọmọ Jeteri, o si pa wọn, o si ta ẹ̀jẹ ogun silẹ li alafia, o si fi ẹ̀jẹ ogun si ara àmure rẹ̀ ti mbẹ li ẹ̀gbẹ rẹ̀, ati si ara salubata rẹ̀ ti mbẹ li ẹsẹ rẹ̀.

6 Nitorina, ki o ṣe gẹgẹ bi ọgbọ́n rẹ, ki o má si jẹ ki ewu ori rẹ̀ ki o sọkalẹ lọ si isa-okú li alafia.

7 Ṣugbọn ki o ṣe ore fun awọn ọmọ Barsillai, ara Gileadi, ki o si jẹ ki nwọn ki o wà ninu awọn ti o jẹun lori tabili rẹ: nitori bẹ̃ni nwọn ṣe tọ̀ mi wá nigbati mo sá kuro niwaju Absalomu, arakunrin rẹ.