39 O si ṣe lẹhin ọdun mẹta, awọn ọmọ-ọdọ Ṣimei meji si lọ sọdọ Akiṣi ọmọ Maaka, ọba Gati. Nwọn si rò fun Ṣimei pe, Wo o, awọn ọmọ-ọdọ rẹ mbẹ ni Gati.
40 Ṣimei si dide, o si di kẹtẹkẹtẹ ni gari, o si lọ, o si mu awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ bọ̀ lati Gati.
41 A si rò fun Solomoni pe, Ṣimei ti lọ lati Jerusalemu si Gati, o si pada bọ̀.
42 Ọba si ranṣẹ, o si pè Ṣimei, o si wi fun u pe, emi kò ti mu ọ fi Oluwa bura, emi kò si ti fi ọ ṣe ẹlẹri, pe, Li ọjọ ti iwọ ba jade, ti iwọ ba si rìn jade lọ nibikibi, ki iwọ ki o mọ̀ dajudaju pe, kikú ni iwọ o kú? iwọ si wi fun mi pe, Ọrọ na ti mo gbọ́, o dara.
43 Ẽ si ti ṣe ti iwọ kò pa ibura Oluwa mọ, ati aṣẹ ti mo pa fun ọ?
44 Ọba si wi fun Ṣimei pe, Iwọ mọ̀ gbogbo buburu ti ọkàn rẹ njẹ ọ lẹri, ti iwọ ti ṣe si Dafidi, baba mi: Oluwa yio si yi buburu rẹ si ori ara rẹ.
45 A o si bukun Solomoni ọba, a o si fi idi itẹ́ Dafidi mulẹ niwaju Oluwa lailai.