8 Si wò o, Ṣimei, ọmọ Gera, ẹyà Benjamimi ti Bahurimu, wà pelu rẹ ti o bú mi ni ẽbu ti o burujù, ni ọjọ́ ti mo lọ si Mahanaimu: ṣugbọn o sọkalẹ wá pade mi ni Jordani, mo si fi Oluwa bura fun u pe, Emi kì yio fi idà pa ọ.
9 Ṣugbọn nisisiyi, máṣe jẹ ki o ṣe alaijiya, nitori ọlọgbọ́n enia ni iwọ, iwọ si mọ̀ ohun ti iwọ o ṣe si i; ṣugbọn ewú ori rẹ̀ ni ki o mu sọkalẹ pẹlu ẹjẹ sinu isa-okú.
10 Dafidi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni ilu Dafidi.
11 Ọjọ ti Dafidi jọba lori Israeli jẹ ogoji ọdun: ni Hebroni o jọba li ọdun meje, ni Jerusalemu o si jọba li ọdun mẹtalelọgbọn.
12 Solomoni si joko lori itẹ Dafidi baba rẹ̀; a si fi idi ijọba rẹ̀ kalẹ gidigidi.
13 Adonijah, ọmọ Haggiti si tọ Batṣeba, iya Solomoni wá, Batṣeba si wipe; Alafia li o ba wá bi? On si wipe, alafia ni.
14 On si wipe, emi ni ọ̀rọ kan ba ọ sọ. On si wipe, Mã wi: