23 Malu mẹwa ti o sanra, ati ogún malu lati inu papa wá, ati ọgọrun agutan, laika agbọ̀nrin, ati egbin, ati ogbúgbu, ati ẹiyẹ ti o sanra.
24 Nitori on li o ṣe alaṣẹ lori gbogbo agbègbe ni iha ihin odò, lati Tifsa titi de Gasa, lori gbogbo awọn ọba ni iha ihin odò: o si ni alafia ni iha gbogbo yi i kakiri.
25 Juda ati Israeli ngbe li alafia, olukuluku labẹ àjara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ́ rẹ̀, lati Dani titi de Beerṣeba, ni gbogbo ọjọ Solomoni.
26 Solomoni si ni ẹgbãji ile-ẹṣin fun kẹkẹ́ rẹ̀, ati ẹgbãfa ẹlẹṣin.
27 Awọn ijoye na si pesè onjẹ fun Solomoni ọba, ati fun gbogbo awọn ti o wá sibi tabili Solomoni ọba, olukuluku li oṣu tirẹ̀: nwọn kò fẹ nkankan kù.
28 Ọkà barle pẹlu, ati koriko fun ẹṣin ati fun ẹṣin sisare ni nwọn mu wá sibiti o gbe wà, olukuluku gẹgẹ bi ilana tirẹ̀.
29 Ọlọrun si fun Solomoni li ọgbọ́n ati oye li ọ̀pọlọpọ, ati oye gbigboro, gẹgẹ bi iyanrin ti o wà leti okun.