25 Juda ati Israeli ngbe li alafia, olukuluku labẹ àjara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ́ rẹ̀, lati Dani titi de Beerṣeba, ni gbogbo ọjọ Solomoni.
26 Solomoni si ni ẹgbãji ile-ẹṣin fun kẹkẹ́ rẹ̀, ati ẹgbãfa ẹlẹṣin.
27 Awọn ijoye na si pesè onjẹ fun Solomoni ọba, ati fun gbogbo awọn ti o wá sibi tabili Solomoni ọba, olukuluku li oṣu tirẹ̀: nwọn kò fẹ nkankan kù.
28 Ọkà barle pẹlu, ati koriko fun ẹṣin ati fun ẹṣin sisare ni nwọn mu wá sibiti o gbe wà, olukuluku gẹgẹ bi ilana tirẹ̀.
29 Ọlọrun si fun Solomoni li ọgbọ́n ati oye li ọ̀pọlọpọ, ati oye gbigboro, gẹgẹ bi iyanrin ti o wà leti okun.
30 Ọgbọ́n Solomoni si bori ọgbọ́n gbogbo awọn ọmọ ila-õrun, ati gbogbo ọgbọ́n Egipti.
31 On si gbọ́n jù gbogbo enia; jù Etani, ara Esra, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara, awọn ọmọ Maholi: okiki rẹ̀ si kàn ni gbogbo orilẹ-ède yíka.