1 HIRAMU, ọba Tire, si rán awọn iranṣẹ rẹ̀ si Solomoni; nitoriti o ti gbọ́ pe, a ti fi ororo yàn a li ọba ni ipò baba rẹ̀: nitori Hiramu ti fẹràn Dafidi li ọjọ rẹ̀ gbogbo.
2 Solomoni si ranṣẹ si Hiramu wipe,
3 Iwọ mọ̀ bi Dafidi, baba mi, kò ti le kọ́ ile fun orukọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ nitori ogun ti o wà yi i ka kiri, titi Oluwa fi fi wọn sabẹ atẹlẹsẹ rẹ̀.
4 Ṣugbọn nisisiyi Oluwa Ọlọrun mi ti fun mi ni isimi niha gbogbo, bẹ̃ni kò si si ọta tabi ibi kan ti o ṣẹ̀.
5 Si kiye si i, mo gbèro lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa Ọlọrun mi, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ fun Dafidi, baba mi pe, Ọmọ rẹ, ti emi o gbe kà ori itẹ́ rẹ ni ipò rẹ, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi.
6 Njẹ nisisiyi, paṣẹ ki nwọn ki o ke igi kedari fun mi lati Lebanoni wá, awọn ọmọ ọdọ mi yio si wà pẹlu awọn ọmọ ọdọ rẹ, iwọ ni emi o si sanwo ọyà awọn ọmọ ọdọ rẹ fun, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti iwọ o wi: nitoriti iwọ mọ̀ pe, kò si ẹnikan ninu wa ti o mọ̀ bi a ti ike igi bi awọn ara Sidoni.