30 Olukuluku ijoko li o ni ayika kẹkẹ́ idẹ mẹrin, ati ọpa kẹkẹ́ idẹ: igun mẹrẹrin rẹ̀ li o ni ifẹsẹtẹ labẹ; labẹ agbada na ni ifẹsẹtẹ didà wà, ni iha gbogbo iṣẹ ọṣọ́ na.
31 Ẹnu rẹ̀ ninu ipari na ati loke jẹ igbọnwọ kan: ṣugbọn ẹnu rẹ̀ yika gẹgẹ bi iṣẹ ijoko na, si jẹ igbọnwọ kan on àbọ: ati li ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbigbẹ́ wà pẹlu alafo ọ̀na arin wọn, nwọn si dọgba ni igun mẹrẹrin, nwọn kò yika.
32 Ati nisalẹ alafo ọ̀na arin, ayika-kẹkẹ́ mẹrin li o wà: a si so ọpa ayika-kẹkẹ́ na mọ ijoko na; giga ayika-kẹkẹ́ kan si jẹ igbọnwọ kan pẹlu àbọ.
33 Iṣẹ ayika-kẹkẹ́ na si dabi iṣẹ kẹkẹ́; igi idalu wọn, ati ibi iho, ati ibi ipade, ati abukala wọn, didà ni gbogbo wọn.
34 Ifẹsẹtẹ mẹrin li o wà fun igun mẹrin ijoko na: ifẹsẹtẹ na si jẹ ti ijoko tikararẹ̀ papã.
35 Ati loke ijoko na, ayika kan wà ti àbọ igbọnwọ: ati loke ijoko na ẹgbẹgbẹti rẹ̀ ati alafo ọ̀na arin rẹ̀ jẹ bakanna.
36 Ati lara iha ẹgbẹti rẹ̀, ati leti rẹ̀, li o gbẹ́ aworan kerubu, kiniun, ati igi-ọpẹ gẹgẹ bi aye olukuluku, ati iṣẹ ọṣọ yikakiri.