34 Ifẹsẹtẹ mẹrin li o wà fun igun mẹrin ijoko na: ifẹsẹtẹ na si jẹ ti ijoko tikararẹ̀ papã.
35 Ati loke ijoko na, ayika kan wà ti àbọ igbọnwọ: ati loke ijoko na ẹgbẹgbẹti rẹ̀ ati alafo ọ̀na arin rẹ̀ jẹ bakanna.
36 Ati lara iha ẹgbẹti rẹ̀, ati leti rẹ̀, li o gbẹ́ aworan kerubu, kiniun, ati igi-ọpẹ gẹgẹ bi aye olukuluku, ati iṣẹ ọṣọ yikakiri.
37 Gẹgẹ bayi li o si ṣe awọn ijoko mẹwẹwa: gbogbo wọn li o si ni didà kanna, iwọ̀n kanna ati titobi kanna.
38 O si ṣe agbada idẹ mẹwa: agbada kan gbà to òji iwọn Bati: agbada kọ̃kan si jẹ igbọnwọ mẹrin: lori ọkọ̃kan ijoko mẹwẹwa na ni agbada kọ̃kan wà.
39 O si fi ijoko marun si apa ọtún ile na, ati marun si apa òsi ile na: o si gbe agbada-nla ka apa ọ̀tún ile na, si apa ila-õrun si idojukọ gusu:
40 Hiramu si ṣe ikoko ati ọkọ́, ati awo-koto. Bẹ̃ni Hiramu si pari gbogbo iṣẹ ti o ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba: