4 Ferese si wà ni ọ̀wọ́ mẹta, oju si ko oju ni ọ̀na mẹta.
5 Gbogbo ilẹkun ati opó si dọgba ni igun mẹrin; oju si ko oju ni ọ̀na mẹta.
6 O si fi ọwọ̀n ṣe iloro: gigùn rẹ̀ jẹ adọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ si jẹ ọgbọ̀n igbọnwọ, iloro kan si wà niwaju rẹ̀: ani ọwọ̀n miran, igi itẹsẹ ti o nipọn si mbẹ niwaju wọn.
7 O si ṣe iloro itẹ nibiti yio ma ṣe idajọ, ani iloro idajọ: a si fi igi kedari tẹ ẹ lati iha kan de keji.
8 Ile rẹ̀ nibiti o ngbe, ni agbala lẹhin ile titi de ọ̀dẹdẹ, si jẹ iṣẹ kanna. Solomoni si kọ́ ile fun ọmọbinrin Farao, ti o ni li aya, bi iloro yi.
9 Gbogbo wọnyi jẹ okuta iyebiye gẹgẹ bi iwọn okuta gbigbẹ́, ti a fi ayùn rẹ́ ninu ati lode, ani lati ipilẹ de ibori-oke ile, bẹ̃ si ni lode si apa agbala nla.
10 Ipilẹ na jẹ okuta iyebiye, ani okuta nlanla, okuta igbọnwọ mẹwa, ati okuta igbọnwọ mẹjọ.