42 Ati irinwo pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n meji, ọ̀wọ́ meji pomegranate fun iṣẹ àwọ̀n kan, lati bò awọn ọpọ́n meji ipari ti mbẹ loke awọn ọwọ̀n;
43 Ati ijoko mẹwa, ati agbada mẹwa lori awọn ijoko na.
44 Agbada nla kan, ati malu mejila labẹ agbada nla.
45 Ati ikoko, ati ọkọ́, ati awo-koto; ati gbogbo ohun-elo wọnyi ti Hiramu ṣe fun ile Oluwa fun Solomoni ọba, jẹ ti idẹ didan.
46 Ni pẹtẹlẹ Jordani ni ọba dà wọn, ni ilẹ amọ̀ ti mbẹ lagbedemeji Sukkoti on Sartani.
47 Solomoni si jọwọ gbogbo ohun-elo na silẹ li alaiwọ̀n, nitori ti nwọn papọju: bẹ̃ni a kò si mọ̀ iwọ̀n idẹ na.
48 Solomoni si ṣe gbogbo ohun-elo ti iṣe ti ile Oluwa: pẹpẹ wura, ati tabili wura, lori eyi ti akara ifihan gbe wà.