1 O si ṣe, bi Solomoni ti pari kikọ́ ile Oluwa, ati ile ọba, ati gbogbo ifẹ Solomoni ti o wù u lati ṣe,
2 Oluwa fi ara hàn Solomoni li ẹrinkeji, gẹgẹ bi o ti fi ara hàn a ni Gibeoni.
3 Oluwa si wi fun u pe, Mo ti gbọ́ adura rẹ ati ẹ̀bẹ rẹ, ti iwọ ti bẹ̀ niwaju mi, mo ti ya ile yi si mimọ́, ti iwọ ti kọ́, lati fi orukọ mi sibẹ titi lai; ati oju mi ati ọkàn mi yio wà nibẹ titi lai.
4 Bi iwọ o ba rìn niwaju mi: bi Dafidi baba rẹ ti rìn, ni otitọ ọkàn, ati ni iduroṣinṣin, lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo ti pa li aṣẹ fun ọ, ti iwọ o si pa aṣẹ mi ati idajọ mi mọ́:
5 Nigbana li emi o fi idi itẹ́ ijọba rẹ mulẹ lori Israeli titi lai, bi mo ti ṣe ileri fun Dafidi baba rẹ, wipe, Iwọ kì yio fẹ ọkunrin kan kù lori itẹ́ Israeli.
6 Ṣugbọn bi ẹnyin o ba yipada lati mã tọ̀ mi lẹhin, ẹnyin, tabi awọn ọmọ nyin, bi ẹnyin kò si pa ofin mi mọ́, ati aṣẹ mi ti mo ti fi si iwaju nyin, ṣugbọn bi ẹ ba lọ ti ẹ si sìn awọn ọlọrun miran, ti ẹ si bọ wọn: