7 Nigbana ni emi o ké Israeli kuro ni ilẹ ti emi fi fun wọn; ati ile yi, ti mo ti yà si mimọ́ fun orukọ mi li emi o gbe sọnù kuro niwaju mi; Israeli yio si di owe ati ifiṣẹsin lãrin gbogbo orilẹ-ède.
8 Ati ile yi, ti o ga, ẹnu o si ya olukuluku ẹniti o kọja lẹba rẹ̀, yio si pòṣe: nwọn o si wipe; ẽṣe ti Oluwa fi ṣe bayi si ilẹ yi ati si ile yi?
9 Nwọn o si dahùn wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ Oluwa Ọlọrun wọn silẹ, ẹniti o mu awọn baba wọn jade ti ilẹ Egipti wá, nwọn gbá awọn ọlọrun miran mú, nwọn si bọ wọn, nwọn si sìn wọn: nitorina ni Oluwa ṣe mu gbogbo ibi yi wá sori wọn.
10 O si ṣe lẹhin ogún ọdun, nigbati Solomoni ti kọ́ ile mejeji tan, ile Oluwa, ati ile ọba.
11 Hiramu, ọba Tire ti ba Solomoni wá igi kedari ati igi firi, ati wura gẹgẹ bi gbogbo ifẹ rẹ̀, nigbana ni Solomoni ọba fun Hiramu ni ogún ilu ni ilẹ Galili.
12 Hiramu si jade lati Tire wá lati wò ilu ti Solomoni fi fun u: nwọn kò si wù u.
13 On si wipe, Ilu kini wọnyi ti iwọ fi fun mi, arakunrin mi? O si pè wọn ni ilẹ Kabulu titi fi di oni yi.