35 Saulu si tẹ pẹpẹ kan fun Oluwa; eyi ni pẹpẹ ti o kọ ṣe fun Oluwa.
36 Saulu wipe, Ẹ jẹ ki a sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ li oru, ki a ba wọn ja titi di imọlẹ owurọ̀, ẹ má jẹ ki a fi ọkunrin kan silẹ ninu wọn. Nwọn si wipe, Ṣe gbogbo eyi ti o tọ loju rẹ. Nigbana ni alufa ni si wipe, Ẹ jẹ ki a sunmọ ihinyi si Ọlọrun.
37 Saulu si bere lọdọ Ọlọrun pe, ki emi ki o sọkalẹ tọ̀ awọn Filistini lọ bi? Iwọ o fi wọn lé Israeli lọwọ́ bi? ṣugbọn kò da a lohùn li ọjọ na.
38 Saulu si wipe Mu gbogbo awọn àgba enia sunmọ ihinyi, ki ẹ mọ̀, ki ẹ si ri ibiti ẹ̀ṣẹ yi wà loni.
39 Nitoripe gẹgẹ bi Oluwa ti wà ti o ti gbà Israeli là bi o tilẹ ṣepe a ri i lara Jonatani ọmọ mi, nitõtọ yio kú. Ṣugbọn ninu gbogbo enia na, kò si ẹniti o da a lohùn.
40 Saulu si wi fun gbogbo awọn Israeli pe, Ẹnyin lọ si apakan, emi ati Jonatani ọmọ mi a si lọ si apakan. Gbogbo enia si wi fun Saulu pe, Ṣe eyi ti o tọ ni oju rẹ.
41 Saulu si wi fun Oluwa Ọlọrun Israeli pe, fun mi ni ibò ti o pé. A si mu Saulu ati Jonatani: ṣugbọn awọn enia na yege.