1 OLUWA si wi fun Samueli pe, Yio ti pẹ to ti iwọ o fi ma kãnu Saulu, nigbati o jẹ pe, mo ti kọ̀ ọ lati ma jọba lori Israeli? Fi ororo kún iwo rẹ, ki o si lọ, emi o rán ọ tọ̀ Jesse ara Betlehemu: nitoriti emi ti ri ọba kan fun ara mi ninu awọn ọmọ rẹ̀.
2 Samueli si wi pe, Emi o ti ṣe lọ? bi Saulu ba gbọ́ yio si pa mi. Oluwa si wi fun u pe, mu ọdọ-malu kan li ọwọ́ rẹ, ki o si wipe, Emi wá rubọ si Oluwa.
3 Ki o si pe Jesse si ibi ẹbọ na, emi o si fi ohun ti iwọ o ṣe hàn ọ: iwọ o si ta ororo si ori ẹniti emi o da orukọ fun ọ.
4 Samueli si ṣe eyi ti Oluwa wi fun u, o sì wá si Betlehemu. Awọn agbà ilu na si bẹ̀ru nitori wiwá rẹ̀, nwọn si wipe, Alafia ki iwọ ba wá si bi?
5 On si dahùn wipe, Alafia ni: emi wá rubọ si Oluwa; ẹ ṣe ara nyin ni mimọ́, ki ẹ si wá pẹlu mi si ibi ẹbọ na. On si yà Jesse sí mimọ́, ati awọn ọmọ rẹ̀, o si pe wọn si ẹbọ na.
6 O si ṣe nigbati nwọn de, o ri Eliabu, o si wipe, nitotọ ẹni-àmi-ororo Oluwa mbẹ niwaju rẹ̀.
7 Ṣugbọn Oluwa wi fun Samueli pe, máṣe wo oju rẹ̀, tabi giga rẹ̀; nitoripe emi kọ̀ ọ: nitoriti Oluwa kì iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn.