29 Dafidi si dahùn wipe, Kini mo ṣe nisisiyi? ko ha ni idi bi?
30 On si yipada kuro lọdọ rẹ̀ si ẹlomiran, o si sọ bakanna: awọn enia na si fi esì fun u gegẹ bi ọ̀rọ iṣaju.
31 Nwọn si gbọ́ ọ̀rọ ti Dafidi sọ, nwọn si sọ gbogbo wọn li oju Saulu: on si ranṣẹ pè e.
32 Dafidi si wi fun Saulu pe, Ki aiya ki o máṣe fò ẹnikẹni nitori rẹ̀; iranṣẹ rẹ yio lọ, yio si ba Filistini yi jà.
33 Saulu si wi fun Dafidi pe, Iwọ kò le tọ Filistini yi lọ lati ba a jà: nitoripe ọdọmọde ni iwọ, on si jẹ jagunjagun lati igba ewe rẹ̀ wá.
34 Dafidi si wi fun Saulu pe, Nigbati iranṣẹ rẹ nṣọ agutan baba rẹ̀, kiniun kan si wá, ati amọtẹkun kan, o si gbe ọdọ agutan kan lati inu agbo.
35 Mo si jade tọ̀ ọ, mo si lù u, mo si gbà a kuro li ẹnu rẹ̀: nigbati o si dide si mi, mo gbá irugbọ̀n rẹ̀ mu, mo si lù u, mo si pa a.