37 Dafidi si wipe, Oluwa ti o gbà mi lọwọ́ kiniun ati lọwọ́ amọtẹkun, on na ni yio gbà mi lọwọ́ Filistini yi. Saulu si wi fun Dafidi pe, Lọ, Oluwa yio si pẹlu rẹ.
38 Saulu si fi gbogbo ihamọra ogun rẹ̀ wọ̀ Dafidi, o si fi ibori idẹ kan bò o li ori; o si fi ẹwu ti a fi irin adarọ pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ ṣe wọ̀ ọ.
39 Dafidi si di ida rẹ̀ mọ ihamọra rẹ̀, on si gbiyanju lati lọ, on kò sa iti dan a wò. Dafidi si wi fun Saulu pe, Emi kò le ru wọnyi lọ, nitoripe emi kò idan a wò. Dafidi si tu wọn kuro li ara rẹ̀.
40 On si mu ọpa rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, o si ṣà okuta marun ti o jọlọ̀ ninu odò, o si fi wọn sinu apò oluṣọ agutan ti o ni, ani sinu asùwọn: kànakana rẹ̀ si wà li ọwọ́ rẹ̀; o si sunmọ Filistini na.
41 Filistini na si mbọ̀, o si nsunmọ Dafidi; ati ọkunrin ti o rù awà rẹ̀ si mbọ̀ niwaju rẹ̀.
42 Nigbati Filistini na si wò, ti o si ri Dafidi, o ṣata rẹ̀: nitoripe ọdọmọdekunrin ni iṣe, o pọn, o si ṣe arẹwa enia.
43 Filistini na si wi fun Dafidi pe, Emi ha nṣe aja bi, ti iwọ fi mu ọpá tọ̀ mi wá? Filistini na si fi Dafidi re nipa awọn ọlọrun rẹ̀.