54 Dafidi si gbe ori Filistini na, o si mu u wá si Jerusalemu; ṣugbọn o fi ihamọra rẹ̀ si inu agọ rẹ̀.
55 Nigbati Saulu si ri Dafidi ti nlọ pade Filistini na, o si bi Abneri oloriogun pe, Abneri, ọmọ tani ọmọde yi iṣe? Abneri si dahun pe, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, ọba, emi kò mọ̀.
56 Ọba si wipe, Iwọ bere ọmọ tali ọmọde na iṣe?
57 Bi Dafidi si ti ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, Abneri si mu u wá siwaju Saulu, ti on ti ori Filistini na lọwọ rẹ̀.
58 Saulu si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ ọmọde yi iṣe? Dafidi si da a li ohùn pe, Emi li ọmọ Jesse iranṣẹ rẹ ara Betlehemu.