27 Dafidi si dide, o lọ, on ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, o si pa igba ọmọkunrin ninu awọn Filistini; Dafidi si mu ẹfa abẹ wọn wá, nwọn si kà wọn pe fun ọba, ki on ki o le jẹ ana ọba. Saulu si fi Mikali ọmọ rẹ obinrin fun u li aya.
28 Saulu si ri o si mọ̀ pe, Oluwa wà pẹlu Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu si fẹ ẹ.
29 Saulu si bẹ̀ru Dafidi siwaju ati siwaju: Saulu si wa di ọtá Dafidi titi.
30 Awọn ọmọ-alade Filistini si jade lọ: o si ṣe, lẹhin igbati nwọn lọ, Dafidi si huwa ọlọgbọ́n ju gbogbo awọn iranṣẹ Saulu lọ; orukọ rẹ̀ si ni iyìn jọjọ.