5 Nitoriti o mu ẹmi rẹ̀ lọwọ rẹ̀, o si pa Filistini na, Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla fun gbogbo Israeli: iwọ ri i, o si yọ̀: njẹ, nitori kini iwọ o ṣe dẹṣẹ̀ si ẹjẹ alaiṣẹ, ti iwọ o fi pa Dafidi laiṣẹ?
6 Saulu si gbọ́ ohùn Jonatani: Saulu si bura pe, Bi Oluwa ti wà lãye a ki yio pa a.
7 Jonatani si pe Dafidi, Jonatani si ro gbogbo ọràn na fun u. Jonatani si mu Dafidi tọ Saulu wá, on si wà niwaju rẹ̀, bi igbà atijọ.
8 Ogun si tun wà sibẹ, Dafidi si jade lọ, o si ba awọn Filistini jà, o si pa wọn pupọ; nwọn si sa niwaju rẹ̀.
9 Ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa wá si bà le Saulu, o si joko ni ile rẹ̀ ton ti ẹṣín rẹ̀ li lọwọ rẹ̀: Dafidi a si ma fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara duru.
10 Saulu ti nwá ọ̀na lati fi ẹṣín na gún Dafidi mọ ogiri: ṣugbọn on si yẹra kuro niwaju Saulu: o si sọ ẹṣín na wọnu ogiri: Dafidi si sa, o si fi ara pamọ li oru na.
11 Saulu si rán onṣẹ si ile Dafidi, lati ma ṣọ ọ ati lati pa a li owurọ: Mikali aya Dafidi si wi fun u pe, Bi iwọ kò ba gbà ẹmi rẹ là li alẹ yi, li ọla li a o pa ọ.