16 Ọkunrin na si wi fun u pe, Jẹ ki wọn sun ọra na nisisiyi, ki o si mu iyekiye ti ọkàn rẹ ba fẹ; nigbana li o da a lohun pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ki iwọ ki o fi i fun mi nisisiyi: bikoṣe bẹ̃, emi o fi agbara gbà a.
17 Ẹṣẹ awọn ọdọmọkunrin na si tobi gidigidi niwaju Oluwa: nitoriti enia korira ẹbọ Oluwa.
18 Ṣugbọn Samueli nṣe iranṣẹ niwaju Oluwa, o ṣe ọmọde, ti a wọ̀ ni efodi ọgbọ.
19 Pẹlupẹlu iya rẹ̀ da aṣọ ileke penpe fun u, a ma mu fun u wá lọdọdun, nigbati o ba bá ọkọ rẹ̀ goke wá lati ṣe irubọ ọdun.
20 Eli sure fun Elkana ati aya rẹ̀ pe ki Oluwa ki o ti ara obinrin yi fun ọ ni iru-ọmọ nipa ibere na ti o bere lọdọ Oluwa. Nwọn si lọ si ile wọn.
21 Oluwa si boju wo Hanna, o si loyun, o bi ọmọkunrin mẹta ati ọmọbinrin meji. Samueli ọmọ na si ndagbà niwaju Oluwa.
22 Eli si di arugbo gidigidi, o si gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ọmọ rẹ̀ ṣe si gbogbo Israeli; ati bi nwọn ti ima ba awọn obinrin sùn, ti nwọn ma pejọ li ẹnu ọ̀na agọ ajọ.