23 O si wi fun wọn pe, Etiri ti emi fi ngbọ́ iru nkan bẹ̃ si nyin? nitoriti emi ngbọ́ iṣe buburu nyin lati ọdọ gbogbo enia yi wá.
24 Bẹ̃kọ, ẹnyin ọmọ mi, nitori ki iṣe ihinrere li emi gbọ́: ẹnyin mu enia Ọlọrun dẹṣẹ̀.
25 Bi ẹnikan ba ṣẹ̀ si ẹnikeji, onidajọ yio ṣe idajọ rẹ̀: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣẹ̀ sí Oluwa, tani yio bẹ̀bẹ fun u? Nwọn kò si fi eti si ohùn baba wọn, nitoriti Oluwa nfẹ pa wọn.
26 Ọmọ na Samueli ndagba, o si ri ojurere lọdọ Oluwa, ati enia pẹlu.
27 Ẹni Ọlọrun kan tọ Eli wá, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, Gbangba ki emi fi ara hàn ile baba rẹ, nigbati nwọn mbẹ ni Egipti ninu ile Farao?
28 Emi ko si yàn a kuro larin gbogbo ẹya Israeli lati jẹ alufa mi, lati rubọ lori pẹpẹ mi, lati fi turari jona, lati wọ efodi niwaju mi, emi si fi gbogbo ẹbọ ti ọmọ Israeli ima fi iná sun fun idile baba rẹ?
29 Eṣe ti ẹnyin fi tapa si ẹbọ ati ọrẹ mi, ti mo pa li aṣẹ ni ibujoko mi: iwọ si bu ọla fun awọn ọmọ rẹ jù mi lọ, ti ẹ si fi gbogbo ãyo ẹbọ Israeli awọn enia mi mu ara nyin sanra?