2 On si wi fun u pe, Ki a má ri i, iwọ kì yio kú: wõ, baba mi ki yio ṣe nkan nla tabi kekere lai sọ ọ li eti mi, njẹ, esi ti ṣe ti baba mi yio fi pa nkan yi mọ fun mi? nkan na kò ri bẹ̃.
3 Dafidi si tun bura, pe, Baba rẹ ti mọ̀ pe, emi ri oju rere li ọdọ rẹ; on si wipe, Máṣe jẹ ki Jonatani ki o mọ̀ nkan yi, ki o má ba binu: ṣugbọn nitotọ, bi Oluwa ti wà, ati bi ọkàn rẹ si ti wà lãye, iṣisẹ̀ kan ni mbẹ larin emi ati ikú.
4 Jonatani si wi fun Dafidi pe, Ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ, wi, emi o si ṣe e fun ọ.
5 Dafidi si wi fun Jonatani pe, Wõ, li ọla li oṣu titun, emi kò si gbọdọ ṣe alai ba ọba joko lati jẹun; ṣugbọn jẹ ki emi ki o lọ, ki emi si fi ara pamọ li oko titi yio fi di aṣalẹ ijọ kẹta.
6 Bi o ba si ṣepe baba rẹ fẹ mi kù, ki o si wi fun u pe, Dafidi bẹ̀ mi lati sure lọ si Betlehemu ilu rẹ̀: nitoripe ẹbọ ọdun kan kò nibẹ fun gbogbo idile na.
7 Bi o ba wipe, O dara, alafia mbẹ fun iranṣẹ rẹ: ṣugbọn bi o ba binu pupọ, njẹ ki iwọ ki o mọ̀ daju pe buburu ni o nrò ninu rẹ̀.
8 Iwọ o si ṣe ore fun iranṣẹ rẹ, nitoripe iwọ ti mu iranṣẹ rẹ wọ inu majẹmu Oluwa pẹlu rẹ; ṣugbọn bi ìwa buburu ba mbẹ li ọwọ mi, iwọ tikararẹ pa mi; ẽṣe ti iwọ o fi mu mi tọ baba rẹ lọ?