2 Saulu si mu ẹgbẹdogun akọni ọkunrin ti a yàn ninu gbogbo Israeli, o si lọ lati wá Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ lori okuta awọn ewurẹ igbẹ.
3 O si de ibi awọn agbo agutan ti o wà li ọ̀na, ihò kan si wà nibẹ, Saulu si wọ inu rẹ̀ lọ lati bo ẹsẹ rẹ̀: Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si mbẹ lẹba iho na.
4 Awọn ọmọkunrin Dafidi si wi fun u pe, Wõ, eyi li ọjọ na ti Oluwa wi fun ọ pe, Wõ, emi o fi ọta rẹ le ọ li ọwọ́, iwọ o si ṣe si i gẹgẹ bi o ti tọ li oju rẹ. Dafidi si dide, o si yọ lọ ike eti aṣọ Saulu.
5 O si ṣe lẹhin eyi, aiya já Dafidi nitoriti on ke eti aṣọ Saulu.
6 On si wi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀ pe, Èwọ̀ ni fun mi lati ọdọ Oluwa wá bi emi ba ṣe nkan yi si oluwa mi, ẹniti a ti fi ami ororo Oluwa yàn, lati nàwọ́ mi si i, nitoripe ẹni-ami-ororo Oluwa ni.
7 Dafidi si fi ọ̀rọ wọnyi da awọn ọmọkunrin rẹ̀ duro, kò si jẹ ki wọn dide si Saulu. Saulu si dide kuro ni iho na, o si ba ọ̀na rẹ̀ lọ.
8 Dafidi si dide lẹhin na, o si jade kuro ninu iho na, o si kọ si Saulu pe, Oluwa mi, ọba. Saulu si wo ẹhìn rẹ̀, Dafidi si doju rẹ̀ bo ilẹ, o si tẹriba fun u.