4 A si sọ fun Saulu pe, Dafidi sa lọ si Gati: on ko si tun wá a kiri mọ.
5 Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Bi o ba jẹ pe emi ri ore ọfẹ loju rẹ, jẹ ki wọn ki o fun mi ni ibi kan ninu awọn ileto wọnni; emi o ma gbe ibẹ: ẽṣe ti iranṣẹ rẹ yio si ma ba ọ gbe ni ilu ọba?
6 Akiṣi si fi Siklagi fun u ni ijọ na; nitorina ni Siklagi fi di ti awọn ọba Juda titi o fi di oni yi.
7 Iye ọjọ ti Dafidi fi joko ni ilu awọn Filistini si jẹ ọdun kan ati oṣu mẹrin.
8 Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ, nwọn si gbe ogun ti awọn ara Geṣuri, ati awọn ara Gesra, ati awọn ara Amaleki: awọn wọnyi li o si ti ngbe ni ilẹ, na nigba atijọ, bi iwọ ti nlọ si Ṣuri titi o fi de ilẹ Egipti.
9 Dafidi si kọlu ilẹ na, ko si fi ọkunrin tabi obinrin silẹ lãye, o si ko agùtan, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ, ati aṣọ, o si yipada o si tọ Akisi wá.
10 Akiṣi si bi i pe, Nibo li ẹnyin gbe rìn si loni? Dafidi si dahun pe, Siha gusu ti Juda ni, ati siha gusun ti Jerameeli, ati siha gusu ti awọn ara Keni: