10 Saulu si bura fun u nipa Oluwa, pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, ìya kan ki yio jẹ ọ nitori nkan yi.
11 Obinrin na si bi i pe, Tali emi o mu wá soke fun ọ? on si wipe, Mu Samueli goke fun mi wá.
12 Nigbati obinrin na si ri Samueli, o kigbe lohùn rara: obinrin na si ba Saulu sọrọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi tan mi jẹ? nitoripe Saulu ni iwọ iṣe.
13 Ọba si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru; kini iwọ ri? obinrin na si wi fun Saulu pe, Emi ri ọlọrun kan nṣẹ́ ti ilẹ wá.
14 O si bi i pe, Ẽ ti ri? o si wipe, Ọkunrin arugbo kan li o nṣẹ́ bọ̀; o si fi agbada bora. Saulu si mọ̀ pe, Samueli ni; o si tẹriba, o si wolẹ.
15 Samueli si wi fun Saulu pe, Eṣe ti iwọ fi yọ mi lẹnu lati mu mi wá oke? Saulu si dahun o si wipe, Ipọnju nla ba mi; nitoriti awọn Filistini mba mi jagun, Ọlọrun si kọ̀ mi silẹ, kò si da mi lohùn mọ, nipa ọwọ́ awọn woli, tabi nipa alá; nitorina li emi si ṣe pè ọ, ki iwọ ki ole fi ohun ti emi o ṣe hàn mi.
16 Samueli si wipe, O ti ṣe bi mi lere nigbati o jẹ pe, Oluwa ti kọ̀ ọ silẹ, o si wa di ọta rẹ?