1 ỌMỌ na Samueli nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli. Ọ̀rọ Oluwa si ṣọwọ́n lọjọ wọnni; ifihàn kò pọ̀.
2 O si ṣe li akoko na, Eli si dubulẹ ni ipo tirẹ̀, oju rẹ̀ bẹrẹ̀ si ṣõkun, tobẹ̃ ti ko le riran.
3 Ki itana Ọlọrun to kú ninu tempeli Oluwa, Samueli dubulẹ nibiti apoti Ọlọrun gbe wà,
4 Oluwa pe Samueli: on si dahun pe, Emi nĩ.
5 O si sare tọ Eli, o si wipe, Emi nĩ; nitori ti iwọ pè mi. On wipe, emi kò pè: pada lọ dubulẹ. O si lọ dubulẹ.