1 AWỌN Filistini si ba Israeli jà: awọn ọkunrin Israeli si sa niwaju awọn Filistini, awọn ti o fi ara pa sì ṣubu li oke Gilboa.
2 Awọn Filistini si nlepa Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kikan; awọn Filistini si pa Jonatani, ati Abinadabu, ati Melkiṣua, awọn ọmọ Saulu.
3 Ijà na si buru fun Saulu gidigidi, awọn tafàtafa si ta a li ọfà, o si fi ara pa pupọ li ọwọ́ awọn tafàtafa.
4 Saulu si wi fun ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ pe, Fa ìda rẹ yọ, ki o si fi i gún mi, ki awọn alaikọla wọnyi ki o má bà wá gún mi, ati ki wọn ki o má ba fi mi ṣe ẹlẹya. Ṣugbọn ẹniti o ru ihamọra rẹ̀ ko fẹ ṣe bẹ̃, nitoripe ẹrù ba a gidigidi. Saulu si mu idà na o si fi pa ara rẹ̀.
5 Nigbati ẹniti o rù ihamọra rẹ̀ si ri pe Saulu kú, on na si fi idà rẹ̀ pa ara rẹ̀, o si kú pẹlu rẹ̀.
6 Saulu si kú, ati awọn ọmọ rẹ̀ mẹta, ati ẹni ti o rù ihamọra rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọkunrin rẹ̀ li ọjọ kanna.