1 APOTI Oluwa wà ni ilẹ awọn Filistini li oṣù meje.
2 Awọn Filistini si pe awọn alufa ati awọn alasọtẹlẹ, wipe, Awa o ti ṣe apoti Oluwa si? sọ fun wa ohun ti awa o fi rán a lọ si ipò rẹ̀.
3 Nwọn si wipe, Bi ẹnyin ba rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, máṣe rán a lọ lofo; ṣugbọn bi o ti wu ki o ri, ẹ ṣe irubọ ẹbi fun u; a o si mu nyin lara da, ẹnyin o si mọ̀ ohun ti o ṣe ti ọwọ́ rẹ̀ kò fi kuro li ara nyin.
4 Nwọn wipe, Kini irubọ na ti a o fi fun u? Nwọn si dahun pe, Iyọdi wura marun, ati ẹ̀liri wura marun, gẹgẹ bi iye ijoye Filistini: nitoripe ajakalẹ arùn kanna li o wà li ara gbogbo nyin, ati awọn ijoye nyin.
5 Nitorina ẹnyin o ya ere iyọdi nyin, ati ere ẹ̀liri nyin ti o bà ilẹ na jẹ; ẹnyin o si fi ogo fun Ọlọrun Israeli: bọya yio mu ọwọ́ rẹ̀ fẹrẹ lara nyin, ati lara awọn ọlọrun nyin, ati kuro lori ilẹ nyin,