1. Sam 6:2-8 YCE

2 Awọn Filistini si pe awọn alufa ati awọn alasọtẹlẹ, wipe, Awa o ti ṣe apoti Oluwa si? sọ fun wa ohun ti awa o fi rán a lọ si ipò rẹ̀.

3 Nwọn si wipe, Bi ẹnyin ba rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, máṣe rán a lọ lofo; ṣugbọn bi o ti wu ki o ri, ẹ ṣe irubọ ẹbi fun u; a o si mu nyin lara da, ẹnyin o si mọ̀ ohun ti o ṣe ti ọwọ́ rẹ̀ kò fi kuro li ara nyin.

4 Nwọn wipe, Kini irubọ na ti a o fi fun u? Nwọn si dahun pe, Iyọdi wura marun, ati ẹ̀liri wura marun, gẹgẹ bi iye ijoye Filistini: nitoripe ajakalẹ arùn kanna li o wà li ara gbogbo nyin, ati awọn ijoye nyin.

5 Nitorina ẹnyin o ya ere iyọdi nyin, ati ere ẹ̀liri nyin ti o bà ilẹ na jẹ; ẹnyin o si fi ogo fun Ọlọrun Israeli: bọya yio mu ọwọ́ rẹ̀ fẹrẹ lara nyin, ati lara awọn ọlọrun nyin, ati kuro lori ilẹ nyin,

6 Njẹ ẽtiṣe ti ẹnyin fi se aiya nyin le, bi awọn ara Egipti ati Farao ti se aiya wọn le? nigbati o ṣiṣẹ iyanu nla larin wọn, nwọn kò ha jẹ ki awọn enia na lọ bi? nwọn si lọ.

7 Nitorina ẹ ṣe kẹkẹ titun kan nisisiyi, ki ẹ si mu abo malu meji ti o nfi ọmu fun ọmọ, eyi ti kò ti igbà ajaga si ọrun ri, ki ẹ si so o mọ kẹkẹ́ na, ki ẹnyin ki o si mu ọmọ wọn kuro lọdọ wọn wá ile.

8 Ki ẹnyin ki o si gbe apoti Oluwa nì ka ori kẹkẹ̀ na, ki ẹnyin ki o si fi ohun elo wura wọnni ti ẹnyin dá fun u nitori ẹbọ ọrẹ irekọja, ninu apoti kan li apakan rẹ̀; ki ẹnyin rán a, yio si lọ.