5 Samueli si wipe, Pe gbogbo Israeli jọ si Mispe, emi o si bẹbẹ si Oluwa fun nyin,
6 Nwọn si pejọ si Mispe, nwọn pọn omi, nwọn si tú u silẹ niwaju Oluwa, nwọn gbawẹ li ọjọ na, nwọn si wi nibẹ pe, Awa ti dẹṣẹ si Oluwa. Samueli si ṣe idajọ awọn ọmọ Israeli ni Mispe.
7 Awọn Filistini si gbọ́ pe, awọn ọmọ Israeli pejọ si Mispe, awọn ijoye Filistini si goke tọ Israeli lọ. Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, nwọn bẹ̀ru awọn Filistini.
8 Awọn ọmọ Israeli si wi fun Samueli pe, Máṣe dakẹ ati ma ke pe Oluwa Ọlọrun wa fun wa, yio si gbà wa lọwọ́ awọn Filistini.
9 Samueli mu ọdọ-agutan kan ti nmu ọmu, o si fi i ru ọtọtọ ẹbọ sisun si Oluwa: Samueli si ke pe Oluwa fun Israeli; Oluwa si gbọ́ ọ.
10 Bi Samueli ti nru ẹbọ sisun na lọwọ́, awọn Filistini si sunmọ Israeli lati ba wọn jà: ṣugbọn Oluwa sán ãrá nla li ọjọ na sori awọn Filistini, o si damu wọn, o si pa wọn niwaju Israeli.
11 Awọn ọkunrin Israeli si jade kuro ni Mispe, nwọn si le awọn Filistini, nwọn si npa wọn titi nwọn fi de abẹ Betkari.