17 On o si mu idamẹwa ninu awọn agutan nyin: ẹnyin o si jasi ẹrú rẹ̀.
18 Ẹnyin o kigbe fun igbala li ọjọ na nitori ọba nyin ti ẹnyin o yàn: Oluwa kì yio gbọ́ ti nyin li ọjọ na.
19 Ṣugbọn awọn enia na kọ̀ lati gbọ́ ohùn Samueli; nwọn si wipe, bẹ̃kọ; awa o ni ọba lori wa;
20 Ani awa o si dabi gbogbo orilẹ-ède; ki ọba wa ki o si ma ṣe idajọ wa, ki o si ma ṣaju wa, ki o si ma ja ogun wa.
21 Samueli si gbọ́ gbogbo ọ̀rọ awọn enia na, o si sọ wọn li eti Oluwa.
22 Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn wọn ki o si fi ọba jẹ fun wọn. Samueli sọ fun awọn ọmọ Israeli pe. Lọ, olukuluku si ilu rẹ̀.