15 Oluwa ti wi leti Samueli ni ijọ kan ki Saulu ki o to de, wipe,
16 Niwoyi ọla emi o ran ọkunrin kan lati ilẹ Benjamini wá si ọ, iwọ o si da ororo si i lori ki o le jẹ olori-ogun Israeli awọn enia mi, yio si gbà awọn enia mi là lọwọ awọn Filistini: nitori emi ti bojuwo awọn enia mi, nitoripe ẹkun wọn ti de ọdọ mi.
17 Nigbati Samueli ri Saulu, Oluwa wi fun u pe, Wo ọkunrin na ti mo ti sọrọ rẹ̀ fun ọ! on ni yio jọba awọn enia mi.
18 Saulu si sunmọ Samueli li ẹnu-ọna ilu, o si wipe, Sọ fun mi, emi bẹ ọ, nibo ni ile arina gbe wà?
19 Samueli da Saulu lohùn o si wipe, emi ni arina na: goke lọ siwaju mi ni ibi giga, ẹ o si ba mi jẹun loni, li owurọ̀ emi o si jẹ ki o lọ, gbogbo eyi ti o wà li ọkàn rẹ li emi o sọ fun ọ.
20 Niti awọn kẹtẹkẹtẹ rẹ ti o ti nù lati iwọn ijọ mẹta wá, má fi ọkàn si wọn; nitoriti nwọn ti ri wọn. Si tani gbogbo ifẹ, Israeli wà? Ki iṣe si ọ ati si ile baba rẹ?
21 Saulu si dahùn o si wipe, Ara Benjamini ki emi iṣe? kekere ninu ẹya Israeli? idile mi kò si rẹhìn ninu gbogbo ẹya Benjamini? ẽsi ti ṣe ti iwọ sọrọ yi si mi?