Joṣ 14 YCE

Pípín Ilẹ̀ Tí Ó Wà Ní Apá Ìwọ̀ Oòrùn Odò Jọrdani

1 WỌNYI si ni ilẹ-iní ti awọn ọmọ Israeli gbà ni iní ni ilẹ Kenaani, ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli pín fun wọn,

2 Keké ni nwọn fi ní ilẹ-iní wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá, fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya ni.

3 Nitori Mose ti fi ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya meji ati àbọ ẹ̀ya li apa keji Jordani: ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni on kò fi ilẹ-iní fun lãrin wọn.

4 Nitoripe ẹ̀ya meji ni ẹ̀ya awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu: nitorina nwọn kò si fi ipín fun awọn ọmọ Lefi ni ilẹ na, bikoṣe ilu lati ma gbé, pẹlu àgbegbe ilu wọn fun ohunọ̀sin wọn ati ohun-iní wọn.

5 Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni awọn ọmọ Israeli ṣe, nwọn si pín ilẹ na.

Wọ́n fún Kalebu ní Hebroni

6 Nigbana ni awọn ọmọ Juda wá sọdọ Joṣua ni Gilgali: Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi si wi fun u pe, Iwọ mọ̀ ohun ti OLUWA wi fun Mose enia Ọlọrun nipa temi tirẹ ni Kadeṣi-barnea.

7 Ẹni ogoji ọdún ni mi nigbati Mose iranṣẹ OLUWA rán mi lati Kadeṣi-barnea lọ ṣamí ilẹ na; mo si mú ìhin fun u wá gẹgẹ bi o ti wà li ọkàn mi.

8 Ṣugbọn awọn arakunrin mi ti o gòke lọ já awọn enia li àiya: ṣugbọn emi tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata.

9 Mose si bura li ọjọ́ na wipe, Nitõtọ ilẹ ti ẹsẹ̀ rẹ ti tẹ̀ nì, ilẹ-iní rẹ ni yio jẹ́, ati ti awọn ọmọ rẹ lailai, nitoriti iwọ tọ̀ OLUWA Ọlọrun mi lẹhin patapata.

10 Njẹ nisisiyi, kiyesi i, OLUWA da mi si gẹgẹ bi o ti wi, lati ọdún marunlelogoji yi wá, lati ìgba ti OLUWA ti sọ ọ̀rọ yi fun Mose, nigbati Israeli nrìn kiri li aginjù: si kiyesi i nisisiyi, emi di ẹni arundilãdọrun ọdún li oni.

11 Sibẹ̀ emi lí agbara li oni gẹgẹ bi mo ti ní li ọjọ́ ti Mose rán mi lọ: gẹgẹ bi agbara mi ti ri nigbana, ani bẹ̃li agbara mi ri nisisiyi, fun ogun, ati lati jade ati lati wọle.

12 Njẹ nitorina fi òke yi fun mi, eyiti OLUWA wi li ọjọ́ na; nitoriti iwọ gbọ́ li ọjọ́ na bi awọn ọmọ Anaki ti wà nibẹ̀, ati ilu ti o tobi, ti o si ṣe olodi: bọya OLUWA yio wà pẹlu mi, emi o si lé wọn jade, gẹgẹ bi OLUWA ti wi.

13 Joṣua si sure fun u; o si fi Hebroni fun Kalebu ọmọ Jefunne ni ilẹ-iní.

14 Nitorina Hebroni di ilẹ-iní Kalebu ọmọ Jefunne ti Kenissi titi di oni-oloni; nitoriti o tọ̀ OLUWA Ọlọrun Israeli lẹhin patapata.

15 Orukọ Hebroni lailai rí a ma jẹ́ Kiriati-arba; Arba jẹ́ enia nla kan ninu awọn ọmọ Anaki. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24