Joṣ 6 YCE

Wíwó Odi Jẹriko

1 (NJẸ a há Jeriko mọ́ gága nitori awọn ọmọ Israeli: ẹnikẹni kò jade, ẹnikẹni kò si wọle.)

2 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Wò o, mo ti fi Jeriko lé ọ lọwọ, ati ọba rẹ̀, ati awọn alagbara akọni.

3 Ẹnyin o si ká ilu na mọ́, gbogbo ẹnyin ologun, ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃kan. Bayi ni iwọ o ṣe ni ijọ́ mẹfa.

4 Alufa meje yio gbé ipè jubeli meje niwaju apoti na: ni ijọ́ keje ẹnyin o si yi ilu na ká lẹ̃meje, awọn alufa yio si fọn ipè wọnni.

5 Yio si ṣe, nigbati nwọn ba fọn ipè jubeli kikan, nigbati ẹnyin ba si gbọ́ iró ipè na, gbogbo awọn enia yio si hó kũ; odi ilu na yio si wó lulẹ, bẹrẹ, awọn enia yio si gòke lọ tàra, olukuluku niwaju rẹ̀.

6 Joṣua ọmọ Nuni si pè awọn alufa, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki alufa meje ki o gbé ipè jubeli meje nì niwaju apoti OLUWA.

7 O si wi fun awọn enia pe, Ẹ kọja, ki ẹ si yi ilu na ká, ki awọn ti o hamọra ki o si kọja niwaju apoti OLUWA.

8 O si ṣe, nigbati Joṣua wi fun awọn enia tán, awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje, kọja niwaju OLUWA nwọn si fọn ipè wọnni: apoti majẹmu OLUWA si tẹle wọn.

9 Awọn ti o hamọra si lọ niwaju awọn alufa, ti nfọn ipè, ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti lẹhin, awọn alufa nlọ nwọn si nfọn ipè.

10 Joṣua si paṣẹ fun awọn enia wipe, Ẹ kò gbọdọ hó bẹ̃li ẹ kò gbọdọ pariwo, bẹ̃li ọ̀rọ kan kò gbọdọ jade li ẹnu nyin, titi ọjọ́ ti emi o wi fun nyin pe, ẹ hó; nigbana li ẹnyin o hó.

11 Bẹ̃li o mu ki apoti OLUWA ki o yi ilu na ká, o yi i ká lẹ̃kan: nwọn si lọ si ibudó, nwọn si wọ̀ ni ibudó.

12 Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, awọn alufa si gbé apoti OLUWA.

13 Awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje niwaju apoti OLUWA nlọ titi, nwọn si nfọn ipè wọnni: awọn ti o hamọra-ogun nlọ niwaju wọn; ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti OLUWA lẹhin, awọn alufa si nfọn ipè bi nwọn ti nlọ.

14 Li ọjọ́ keji nwọn yi ilu na ká lẹ̃kan, nwọn si pada si ibudó: bẹ̃ni nwọn ṣe ni ijọ́ mẹfa.

15 O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn dide ni kùtukutu li afẹmọjumọ́, nwọn si yi ilu na ká gẹgẹ bi ti iṣaju lẹ̃meje: li ọjọ́ na nikanṣoṣo ni nwọn yi ilu na ká lẹ̃meje.

16 O si ṣe ni ìgba keje, nigbati awọn alufa fọn ipè, ni Joṣua wi fun awọn enia pe, Ẹ hó; nitoriti OLUWA ti fun nyin ni ilu na.

17 Ilu na yio si jẹ́ ìyasọtọ si OLUWA, on ati gbogbo ohun ti mbẹ ninu rẹ̀: kìki Rahabu panṣaga ni yio là, on ati gbogbo awọn ti mbẹ ni ile pẹlu rẹ̀, nitoriti o pa awọn onṣẹ ti a rán mọ́.

18 Ati ẹnyin, bi o ti wù ki o ri, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu ohun ìyasọtọ, ki ẹ má ba yà a sọ̀tọ tán ki ẹ si mú ninu ohun ìyasọtọ na; ẹnyin a si sọ ibudó Israeli di ifibu, ẹnyin a si mu iyọnu bá a.

19 Ṣugbọn gbogbo fadakà, ati wurà, ati ohunèlo idẹ ati ti irin, mimọ́ ni fun OLUWA: nwọn o wá sinu iṣura OLUWA.

20 Bẹ̃li awọn enia na hó, nigbati awọn alufa fọn ipè: o si ṣe, nigbati awọn enia gbọ́ iró ipè, ti awọn enia si hó kũ, odi na wólulẹ bẹrẹ, bẹ̃li awọn enia wọ̀ inu ilu na lọ, olukuluku tàra niwaju rẹ̀, nwọn si kó ilu na.

21 Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ohun ti o wà ni ilu na run, ati ọkunrin ati obinrin, ati ewe ati àgba, ati akọ-mãlu, ati agutan, ati kẹtẹkẹtẹ.

22 Ṣugbọn Joṣua sọ fun awọn ọkunrin meji ti o ti ṣe amí ilẹ na pe, Ẹ lọ si ile panṣaga nì, ki ẹ si mú obinrin na jade nibẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní, gẹgẹ bi ẹnyin ti bura fun u.

23 Awọn ọmọkunrin ti o ṣamí si wọle, nwọn si mú Rahabu jade, ati baba rẹ̀, ati iya rẹ̀, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní, nwọn si mú gbogbo awọn ibatan rẹ̀ jade; nwọn si fi wọn si ẹhin ibudó Israeli.

24 Nwọn si fi iná kun ilu na ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀; kìki fadakà, ati wurà, ati ohunèlo idẹ ati irin, ni nwọn fi sinu iṣura ile OLUWA.

25 Joṣua si gbà Rahabu panṣaga là, ati ara ile baba rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; o si joko lãrin Israeli titi di oni-oloni; nitoriti o pa awọn onṣẹ mọ́ ti Joṣua rán lọ ṣamí Jeriko.

26 Joṣua si gégun li akokò na wipe, Egún ni fun ọkunrin na niwaju OLUWA ti yio dide, ti yio si kọ ilu Jeriko yi: pẹlu ikú akọ́bi rẹ̀ ni yio fi pilẹ rẹ̀, ati pẹlu ikú abikẹhin rẹ̀ ni yio fi gbé ilẹkun ibode rẹ̀ ró.

27 Bẹ̃ni OLUWA wà pẹlu Joṣua; okikí rẹ̀ si kàn ká gbogbo ilẹ na.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24