Joṣ 15 YCE

Ilẹ̀ Tí Wọ́n Pín fún Ẹ̀yà Juda

1 ILẸ ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn si dé àgbegbe Edomu, ni aginjù Sini, ni ìha gusù, ni apa ipẹkun gusù.

2 Ati àla gusù wọn ni lati eti Okun Iyọ̀ lọ, lati ibi kọ̀rọ omi nì lọ ti o dojukọ ìha gusù:

3 O si lọ si apa gusù òke Akrabbimu, o si lọ si Sini, o si gòke lọ ni ìha gusù Kadeṣi-barnea, o si lọ ni ìha Hesroni, o si gòke lọ si Adari, o si yiká lọ dé Karka:

4 Lati ibẹ̀ o lọ dé Asmoni, o si nà lọ si odò Egipti; opín ilẹ na si yọ si okun: eyi ni yio jẹ́ àla ni gusù nyin.

5 Ati àla ìha ìla-õrùn ni Okun Iyọ̀, ani titi dé ipẹkun Jordani. Ati àla apa ariwa ni lati kọ̀rọ okun nì wá dé ipẹkun Jordani:

6 Àla na si gòke lọ si Beti-hogla, o si kọja lọ ni ìha ariwa Beti-araba; àla na si gòke lọ si okuta Bohani ọmọ Reubeni:

7 Àla na si gòke lọ si Debiri lati afonifoji Akoru, ati bẹ̃ lọ si ìha ariwa, ti o dojukọ Gilgali, ti mbẹ niwaju òke Adummimu, ti mbẹ ni ìha gusù odò na: àla si kọja si apa omi Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Eni-rogeli:

8 Àla na si gòke lọ si ìha afonifoji ọmọ Hinnomu si ìha gusù ti Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): àla na si gòke lọ si ori òke nla ti mbẹ niwaju afonifoji Hinnomu ni ìha ìwọ-õrùn, ti mbẹ ni ipẹkun afonifoji Refaimu ni ìha ariwa:

9 A si fà àla na lati ori òke lọ si isun omi Neftoa, o si nà lọ si ilu òke Efroni; a si fà àla na lọ si Baala, (ti iṣe Kirjati-jearimu:)

10 Àla na yi lati Baala lọ si ìha ìwọ-õrùn si òke Seiri, o si kọja lọ si ẹba òke Jearimu (ti ṣe Kesaloni), ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Beti-ṣemeṣi, o si kọja lọ si Timna:

11 Àla na si kọja lọ si ẹba Ekroni si ìha ariwa: a si fà àla na lọ dé Ṣikroni, o si kọja lọ si òke Baala, o si yọ si Jabneeli; àla na si yọ si okun.

12 Àla ìwọ-õrùn si dé okun nla, ati àgbegbe rẹ̀. Eyi ni àla awọn ọmọ Juda yiká kiri gẹgẹ bi idile wọn.

Kalebu Ṣẹgun Heburoni ati Debiri

13 Ati fun Kalebu ọmọ Jefunne li o fi ipín fun lãrin awọn ọmọ Juda, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA fun Joṣua, ani Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni); Arba si ni baba Anaki.

14 Kalebu si lé awọn ọmọ Anaki mẹta kuro nibẹ̀, Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki.

15 O si gòke lati ibẹ̀ tọ̀ awọn ara Debiri lọ: orukọ Debiri lailai rí ni Kiriati-seferi.

16 Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o sì kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya.

17 Otnieli ọmọ Kenasi, arakunrin Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya.

18 O si ṣe, bi Aksa ti dé ọdọ rẹ̀, o mu u bère ọ̀rọ kan lọwọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́?

19 On si dahùn pe, Ta mi li ọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fun mi ni isun omi pẹlu. O si fi isun òke ati isun isalẹ fun u.

Àwọn Ìlú Ńláńlá Tí Wọ́n Wà ní Juda

20 Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Juda gẹgẹ bi idile wọn.

21 Ilu ipẹkun ẹ̀ya awọn ọmọ Juda li àgbegbe Edomu ni Gusù ni Kabseeli, ati Ederi, ati Jaguri;

22 Ati Kina, ati Dimona, ati Adada;

23 Ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Itnani;

24 Sifu, ati Telemu, ati Bealotu;

25 Ati Haṣori-hadatta, ati Keriotu-hesroni (ti iṣe Hasori);

26 Amamu, ati Ṣema, ati Molada;

27 Ati Hasari-gada, ati Heṣmoni, ati Beti-peleti;

28 Ati Hasari-ṣuali, ati Beeri-ṣeba, ati Bisi-otia;

29 Baala, ati Iimu, ati Esemu;

30 Ati Eltoladi, ati Kesili, ati Horma;

31 Ati Siklagi, ati Madmanna, ati Sansanna;

32 Ati Lebaotu, ati Ṣilhimu, ati Aini, ati Rimmoni: gbogbo ilu na jasi mọkandilọgbọ̀n, pẹlu ileto wọn.

33 Ni pẹtẹlẹ̀, Eṣtaoli, ati Sora, ati Aṣna;

34 Ati Sanoa, ati Eni-gannimu Tappua, ati Enamu;

35 Jarmutu, ati Adullamu, Soko, ati Aseka;

36 Ati Ṣaaraimu, ati Aditaimu, ati Gedera, ati Gederotaimu; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn.

37 Senani, ati Hadaṣa, ati Migdali-gadi;

38 Ati Dilani, ati Mispe, ati Jokteeli;

39 Lakiṣi, ati Boskati, ati Egloni;

40 Ati Kabboni, ati Lamamu, ati Kitliṣi;

41 Ati Gederotu, Beti-dagoni, ati Naama, ati Makkeda; ilu mẹrindilogun pẹlu ileto wọn.

42 Libna, ati Eteri, ati Aṣani;

43 Ati Ifta, ati Aṣna, ati Nesibu;

44 Ati Keila, ati Aksibu, ati Mareṣa; ilu mẹsan pẹlu ileto wọn.

45 Ekroni, pẹlu awọn ilu rẹ̀ ati awọn ileto rẹ̀:

46 Lati Ekroni lọ ani titi dé okun, gbogbo eyiti mbẹ leti Aṣdodu, pẹlu ileto wọn.

47 Aṣdodu, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; Gasa, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; dé odò Egipti, ati okun nla, ati àgbegbe rẹ̀.

48 Ati ni ilẹ òke, Ṣamiri, ati Jattiri, ati Soko;

49 Ati Dana, ati Kiriati-sana (ti ṣe Debiri);

50 Ati Anabu, ati Eṣtemo, ati Animu;

51 Ati Goṣeni, ati Holoni, ati Gilo; ilu mọkanla pẹlu ileto wọn.

52 Arabu, ati Duma, ati Eṣani;

53 Ati Janimu, ati Beti-tappua, ati Afeka;

54 Ati Humta, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni), ati Siori; ilu meṣan pẹlu ileto wọn.

55 Maoni, Karmeli, ati Sifu, ati Juta;

56 Ati Jesreeli, ati Jokdeamu, ati Sanoa;

57 Kaini, Gibea, ati Timna; ilu mẹwa pẹlu ileto wọn.

58 Halhulu, Beti-suru, ati Gedori;

59 Ati Maarati, ati Beti-anotu, ati Eltekoni; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn.

60 Kiriati-baali (ti iṣe Kiriati-jearimu), ati Rabba; ilu meji pẹlu ileto wọn.

61 Li aginjù, Beti-araba, Middini, ati Sekaka;

62 Ati Nibṣani, ati Ilu Iyọ̀, ati Eni-gedi; ilu mẹfa pẹlu ileto wọn.

63 Bi o si ṣe ti awọn Jebusi nì, awọn ara Jerusalemu, awọn ọmọ Juda kò le lé wọn jade: ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Juda gbé ni Jerusalemu, titi di oni-oloni.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24