Joṣ 7 YCE

Ẹ̀ṣẹ̀ Akani

1 ṢUGBỌN awọn ọmọ Israeli dẹ́ṣẹ kan niti ohun ìyasọtọ: nitoriti Akani, ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀ya Juda, mú ninu ohun ìyasọtọ: ibinu OLUWA si rú si awọn ọmọ Israeli.

2 Joṣua si rán enia lati Jeriko lọ si Ai, ti mbẹ lẹba Beti-afeni, ni ìla-õrùn Beti-eli, o si wi fun wọn pe, Ẹ gòke lọ ki ẹ si ṣamí ilẹ na. Awọn enia na gòke lọ nwọn si ṣamí Ai.

3 Nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, nwọn si wi fun u pe, Má ṣe jẹ ki gbogbo enia ki o gòke lọ; ṣugbọn jẹ ki ìwọn ẹgba tabi ẹgbẹdogun enia ki o gòke lọ ki nwọn si kọlù Ai; má ṣe jẹ ki gbogbo enia lọ ṣiṣẹ́ nibẹ̀; nitori diẹ ni nwọn.

4 Bẹ̃ni ìwọn ẹgbẹdogun enia gòke lọ sibẹ̀: nwọn si sá niwaju awọn enia Ai.

5 Awọn enia Ai pa enia mẹrindilogoji ninu wọn: nwọn si lepa wọn lati ẹnubode titi dé Ṣebarimu, nwọn si pa wọn bi nwọn ti nsọkalẹ: àiya awọn enia na já, o si di omi.

6 Joṣua si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si dojubolẹ niwaju apoti OLUWA titi di aṣalẹ, on ati awọn àgba Israeli; nwọn si bù ekuru si ori wọn.

7 Joṣua si wipe, Yẽ, Oluwa ỌLỌRUN, nitori kini iwọ fi mú awọn enia yi kọja Jordani, lati fi wa lé ọwọ́ awọn Amori, lati pa wa run? awa iba mọ̀ ki a joko ni ìha keji ọhún Jordani!

8 A, Oluwa, kili emi o wi, nigbati Israeli pa ẹhin wọn dà niwaju awọn ọtá wọn!

9 Nitoriti awọn ara Kenaani ati gbogbo awọn ara ilẹ na yio gbọ́, nwọn o si yi wa ká, nwọn o si ke orukọ wa kuro li aiye: kini iwọ o ha ṣe fun orukọ nla rẹ?

10 OLUWA si wi fun Joṣua pe, Dide; ẽṣe ti iwọ fi doju rẹ bolẹ bayi?

11 Israeli ti dẹ̀ṣẹ, nwọn si ti bà majẹmu mi jẹ́ ti mo palaṣẹ fun wọn: ani nwọn ti mú ninu ohun ìyasọtọ nì; nwọn si jale, nwọn si ṣe agabagebe pẹlu, ani nwọn si fi i sinu ẹrù wọn.

12 Nitorina ni awọn ọmọ Israeli kò ṣe le duro niwaju awọn ọtá wọn, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọtá wọn, nitoriti nwọn di ẹni ifibu: emi ki yio wà pẹlu nyin mọ́, bikoṣepe ẹnyin pa ohun ìyasọtọ run kuro lãrin nyin.

13 Dide, yà awọn enia na simimọ́, ki o si wipe, Ẹ yà ara nyin simimọ́ fun ọla: nitori bayi li OLUWA, Ọlọrun Israeli wipe; Ohun ìyasọtọ kan mbẹ ninu rẹ, iwọ Israeli: iwọ ki yio le duro niwaju awọn ọtá rẹ, titi ẹnyin o fi mú ohun ìyasọtọ na kuro ninu nyin.

14 Nitorina li owurọ̀ a o mú nyin wá gẹgẹ bi ẹ̀ya nyin: yio si ṣe, ẹ̀ya ti OLUWA ba mú yio wá gẹgẹ ni idile idile: ati idile ti OLUWA ba mú yio wá li agbagbole; ati agbole ti OLUWA ba mú yio wá li ọkunrin kọkan.

15 Yio si ṣe, ẹniti a ba mú pẹlu ohun ìyasọtọ na, a o fi iná sun u, on ati ohun gbogbo ti o ní: nitoriti o rú ofin OLUWA, ati nitoriti o si hù ìwakiwa ni Israeli.

16 Bẹ̃ni Joṣua dide ni kùtukutu owurọ̀, o si mú Israeli wá gẹgẹ bi ẹ̀ya wọn; a si mú ẹ̀ya Juda:

17 O si mú idile Juda wá; a si mu idile Sera: o si mú idile Sera wá li ọkunrin kọkan; a si mú Sabdi:

18 O si mú ara ile rẹ̀ li ọkunrin kọkan; a si mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ninu, ẹ̀ya Judah.

19 Joṣua si wi fun Akani pe, Ọmọ mi, mo bẹ̀ ọ, fi ogo fun OLUWA, Ọlọrun Israeli, ki o si jẹwọ fun u; ki o si sọ fun mi nisisiyi, ohun ti iwọ se; má ṣe pa a mọ́ fun mi.

20 Akani si da Joṣua lohùn, o si wipe, Nitõtọ ni mo ṣẹ̀ si OLUWA, Ọlọrun Israeli, bayi bayi ni mo ṣe:

21 Nigbati mo ri ẹ̀wu Babeli kan daradara ninu ikogun, ati igba ṣekeli fadakà, ati dindi wurà kan oloṣuwọn ãdọta ṣekeli, mo ṣojukokoro wọn, mo si mú wọn; sawò o, a fi wọn pamọ́ ni ilẹ lãrin agọ́ mi, ati fadakà na labẹ rẹ̀.

22 Joṣua si rán onṣẹ, nwọn si sare wọ̀ inu agọ́ na; si kiyesi i, a fi i pamọ́ ninu agọ́ rẹ̀, ati fadakà labẹ rẹ̀.

23 Nwọn si mú wọn jade lãrin agọ́ na, nwọn si mú wọn wá sọdọ Joṣua, ati sọdọ gbogbo awọn ọmọ Israeli, nwọn si fi wọn lelẹ niwaju OLUWA.

24 Joṣua, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si mú Akani ọmọ Sera, ati fadakà na, ati ẹ̀wu na, ati dindi wurà na, ati awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ati akọ-mãlu rẹ̀, ati kẹtẹkẹtẹ rẹ̀, ati agutan rẹ̀, ati agọ́ rẹ̀, ati ohun gbogbo ti o ní; nwọn si mú wọn lọ si ibi afonifoji Akoru.

25 Joṣua si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yọ wa lẹnu? OLUWA yio yọ iwọ na lẹnu li oni yi. Gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta pa; nwọn si dánasun wọn, nwọn sọ wọn li okuta.

26 Nwọn si kó òkiti okuta nla kan lé e lori titi di oni-oloni; OLUWA si yipada kuro ninu imuna ibinu rẹ̀. Nitorina li a ṣe npè orukọ ibẹ̀ li Afonifoji Akoru, titi di oni-oloni.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24